ترجمة سورة المجادلة

الترجمة اليورباوية

ترجمة معاني سورة المجادلة باللغة اليورباوية من كتاب الترجمة اليورباوية.
من تأليف: أبو رحيمة ميكائيل أيكوييني .

Dájúdájú Allāhu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ (obìnrin) t’ó ń bá ọ ṣe àríyànjiyàn nípa ọkọ rẹ̀, tí ó sì ń ṣàròyé fún Allāhu. Allāhu sì ń gbọ ìsọ̀rọ̀gbèsì ẹ̀yin méjèèjì. Dájúdájú Allāhu ni Olùgbọ́, Olùríran.
Àwọn t’ó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn nínú yín, àwọn ìyàwó kì í ṣe ìyá wọn. Kò sí ẹni tí ó jẹ́ ìyá wọn bí kò ṣe ìyá tí ó bí wọn lọ́mọ. Dájúdájú wọ́n ń sọ aburú nínú ọ̀rọ̀ àti ọ̀rọ̀ irọ́. Dájúdájú Allāhu ni Alámòójúkúrò, Aláforíjìn.
____________________
Kíyè sí i, òfin t’ó ṣe é ní èèwọ̀ fún ọkọ láti fi ẹ̀yìn ìyàwó rẹ̀ wé ẹ̀yìn ìyá rẹ̀, òfin náà l’ó ṣe é ní èèwọ̀ fún un láti fi wé ẹ̀yìn ìyá t’ó fún un ní ọyàn mú ní kékeré nígbà tí kò tí ì já l’ẹ́nu ọyàn.
Àwọn t’ó ń fi ẹ̀yìn ìyàwó wọn wé ti ìyá wọn, lẹ́yìn náà tí wọ́n ń ṣẹ́rí kúrò níbi ohun tí wọ́n sọ, wọn máa tú ẹrú kan sílẹ̀ lóko ẹrú ṣíwájú kí àwọn méjèèjì tó lè súnmọ́ ara wọn. Ìyẹn ni À ń fi ṣe wáàsí fun yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹni tí kò bá rí (ẹrú), ó máa gba ààwẹ̀ oṣù méjì ní tẹ̀léǹtẹ̀lé ṣíwájú kí àwọn méjèèjì t’ó lè súnmọ́ ara wọn. Ẹni tí kò bá ní agbára (ààwẹ̀), ó máa bọ́ ọgọ́ta tálíkà. Ìyẹn nítorí kí ẹ lè ní ìgbàgbọ́ òdodo nínú Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Ìwọ̀nyí sì ni àwọn ẹnu-àlà (òfin) tí Allāhu gbé kalẹ̀ fún ẹ̀dá. Ìyà ẹlẹ́ta-eléro sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Dájúdájú àwọn t’ó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, A óò yẹpẹrẹ wọn gẹ́gẹ́ bí A ṣe yẹpẹrẹ àwọn t’ó ṣíwájú wọn. A kúkú ti sọ àwọn āyah t’ó yanjú kalẹ̀. Ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá sì wà fún àwọn aláìgbàgbọ́.
Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde, Ó sì máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́. Allāhu ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀, àwọn sì gbàgbé rẹ̀. Allāhu sì ni Arínú-róde gbogbo n̄ǹkan.
Ṣé o ò rí i pé dájúdájú Allāhu mọ ohunkóhun t’ó wà nínú àwọn sánmọ̀ àti ohunkóhun t’ó wà nínú ilẹ̀ ni? Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn. Wọ́n kéré sí ìyẹn, wọ́n tún pọ̀ (ju ìyẹn) àfi kí Ó wà pẹ̀lú wọn ní ibikíbi tí wọ́n bá wà. Lẹ́yìn náà, Ó máa fún wọn ní ìró ohun tí wọ́n ṣe níṣẹ́ ní Ọjọ́ Àjíǹde. Dájúdájú Allāhu ni Onímọ̀ nípa gbogbo n̄ǹkan.
____________________
Àwọn kristiẹni sọ pé, “Āyah yìí tako sūrah Ƙọ̄f; 50:16.” Bákan náà, àwọn sūfī sọ pé, “Pẹ̀lú äyah yìí kò sí ibi tí Pàápàá Bíbẹ Ọlọ́hun kò sí!” Àwọn igun méjèèjì ti gbé e gbági. Ọ̀rọ̀ kò sì rí bí wọ́n ti sọ.
Ní àkọ́kọ́ ná, kò sí àtakò láààrin āyah yìí àti sūrah Ƙọ̄f; 50:16. Bákan náà, āyah yìí kò túmọ̀ sí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà lórí ilẹ̀ ayé tàbí pé Pàápàá Bíbẹ Allāhu wà pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan. Tí Allāhu bá ṣe ìkejì ẹnì kan, tàbí Ó ṣe ìkẹta ẹni méjì, tí a sì mọ̀ pé Ọ̀kan ṣoṣo ni Pàápàá Bíbẹ Allāhu, tí àwa ẹ̀dá rẹ̀ sì pọ̀ ní òǹkà, èyí ti túmọ̀ sí pé gbólóhùn àkànlò ni gbólóhùn “Kò sí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ kan láààrin ẹni mẹ́ta àfi kí Allāhu ṣe ìkẹrin wọn àti ẹni márùn-ún àfi kí Ó ṣe ìkẹfà wọn.” àti gbólóhùn “Ó wà pẹ̀lú yín ní ibikíbi tí ẹ bá wà.” (sūrah al-Hadīd; 57:4)
Wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ kò túmọ̀ sí sísọ Pàápàá Allāhu di púpọ̀ bí ẹ̀dá, kò sì túmọ̀ sí sísọ Allāhu di Ẹni tí kò níí wà lórí Ìtẹ́-Ọlá Rẹ̀ lókè sánmọ̀ keje, bí kò ṣe pé wíwà Allāhu pẹ̀lú ẹ̀dá Rẹ̀ ni pé, “Allāhu ń gbọ́ ohùn ẹ̀dá”, “Ó ń rí ẹ̀dá”, “Ó mọ ẹ̀dá”, “Ó ń ṣọ́ ẹ̀dá”. Èyí wà ní ìbámu sí sūrah Tọ̄hā; 20:46, sūrah at-Tọlāƙ; 65:12 àti sūrah al-Mulk; 67: 16 àti 17.
Ṣíwájú sí i, nínú sūrah Ƙọ̄f; 50:16 ìsúnmọ́ tí Allāhu súnmọ́ ẹ̀dá ju isan ọrùn rẹ̀ lọ dúró fún bí àwọn mọlāika olùgbọ̀rọ̀-sílẹ̀ lẹ́nu ẹ̀dá ṣe súnmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan tó. Èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 17 àti 18 nínú sūrah náà. Bákan náà, nínú sūrah al-Wāƙi‘ah; 56:85 ìsúnmọ́ tí Allāhu súnmọ́ ẹ̀dá ju bí a ṣe súnmọ́ ara wa lọ dúró fún bí àwọn mọlāika olùgbẹ̀mí-ẹ̀dá ṣe máa súnmọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan ní àkókò tí ẹ̀mí bá fẹ́ jáde lára ẹ̀dá. Èyí rinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ nínú āyah 83 àti 84 nínú sūrah náà. Nítorí náà, ìsúnmọ́ tí Allāhu ń tọ́ka sí nínú àwọn āyah wọ̀nyẹn àti irú wọn mìíràn kò túmọ̀ sí ìsọ̀kalẹ̀ Allāhu wá sí inú isan ọrùn ẹ̀dá, bí kò ṣe pé àwọn mọlāika ni ọ̀rọ̀ náà kàn. Allāhu sì tún fi ìmọ̀ Rẹ̀, ìríran Rẹ̀, agbára Rẹ̀ àti ààbò Rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn mọlāika náà. Wàyí, sūrah al-’Ani‘ām; 6:61 àti 62 ti yanjú gbogbo àlàyé ọ̀rọ̀ yìí.
Ṣé o ò rí àwọn tí A kọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ fún, lẹ́yìn náà tí wọ́n tún padà síbi ohun tí A kọ̀ fún wọn. Wọ́n ń bára wọn sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Nígbà tí wọ́n bá sì dé ọ̀dọ̀ rẹ, wọn yóò kí ọ ní kíkí tí Allāhu kò fi kí ọ. Wọ́n sì ń wí sínú ẹ̀mí wọn pé: "Kí ni kò jẹ́ kí Allāhu jẹ wá níyà lórí ohun tí à ń wí (ní ìkọ̀kọ̀)!" Iná Jahnamọ máa tó wọn. Wọ́n máa wọ inú rẹ̀. Ìkángun náà sì burú.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá ń bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀, ẹ má ṣe sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí ẹ̀ṣẹ̀, àbòsí àti ìyapa Òjíṣẹ́. Ẹ bára yín sọ ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ lórí iṣẹ́ rere àti ìbẹ̀rù Allāhu. Ẹ bẹ̀rù Allāhu, Ẹni tí wọn yóò ko yín jọ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.
Dájúdájú ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ (burúkú) ń wá láti ọ̀dọ̀ Èṣù nítorí kí ó lè kó ìbànújẹ́ bá àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo. Kò sì lè fi kiní kan kó ìnira bá wọn àfi pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Allāhu. Allāhu sì ni kí àwọn onígbàgbọ́ òdodo gbáralé.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí wọ́n bá sọ fun yín pé kí ẹ gbara yín láyè nínú àwọn ibùjókòó, ẹ gbara yín láyè. Allāhu yóò f’àyè gbà yín. Nígbà tí wọ́n bá sọ pé: "Ẹ dìde (síbi iṣẹ́ rere)." Ẹ dìde (sí i). Allāhu yóò ṣàgbéga àwọn ipò fún àwọn t’ó gbàgbọ́ ní òdodo àti àwọn tí A fún ní ìmọ̀ nínú yín. Allāhu sì ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, nígbà tí ẹ bá bá Òjíṣẹ́ sọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ, ẹ fi ọrẹ títa ṣíwájú ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín. Ìyẹn lóore jùlọ fun yín. Ó sì fọ̀ yín mọ́ jùlọ. Tí ẹ ò bá sì rí (ọrẹ), dájúdájú Allāhu ni Aláforíjìn, Àṣàkẹ́-ọ̀run.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah al-Hujurọ̄t; 49:7.
Ṣé ẹ̀ ń páyà (òṣì) níbi kí ẹ máa tí ọrẹ ṣíwájú àwọn ọ̀rọ̀ àtẹ̀sọ yín ni? Nígbà tí ẹ ò ṣe é, Allāhu sì gba ìronúpìwàdà yín. Nítorí náà, ẹ kírun, ẹ yọ Zakāh. Ẹ tẹ̀lé ti Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀. Allāhu ni Alámọ̀tán nípa ohun tí ẹ̀ ń ṣe níṣẹ́.
Ṣé o ò rí àwọn t’ó mú ìjọ kan tí Allāhu bínú sí ní ọ̀rẹ́? Wọn kì í ṣe ara yín, wọn kò sì jẹ́ ara wọn. Wọ́n yó sì máa búra lórí irọ́, wọ́n sì mọ̀.
Allāhu ti pèsè ìyà líle dè wọ́n. Dájúdájú ohun tí wọ́n ń ṣe níṣẹ́ burú.
Wọ́n fi ìbúra wọn ṣe ààbò; wọ́n sì ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu. Nítorí náà, ìyà tí í yẹpẹrẹ ẹ̀dá wà fún wọn.
Àwọn dúkìá wọn àti àwọn ọmọ wọn kò níí fi kiní kan rọ̀ wọ́n lọ́rọ̀ ní ọ̀dọ̀ Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni èrò inú Iná. Olùṣegbére sì ni wọ́n nínú rẹ̀.
Ní ọjọ́ tí Allāhu yóò gbé gbogbo wọn dìde pátápátá, wọn yó sì máa búra fún Un gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń búra fun yín. Wọ́n ń lérò pé dájúdájú àwọn ti rí n̄ǹkan ṣe. Gbọ́! Dájúdájú àwọn, àwọn ni òpùrọ́.
Èṣù jẹ gàba lé wọn lórí. Ó sì mú wọn gbàgbé ìrántí Allāhu. Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Èṣù. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ èṣù, àwọn ni ẹni òfò.
Dájúdájú àwọn t’ó ń yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀, àwọn wọ̀nyẹn wà nínú àwọn olùyẹpẹrẹ jùlọ.
Allāhu kọ ọ́ pé: "Dájúdájú Mo máa borí; Èmi àti àwọn Òjíṣẹ́ Mi." Dájúdájú Allāhu ni Alágbára, Olùborí.
O ò níí rí ìjọ kan t’ó gbàgbọ́ nínú Allāhu àti Ọjọ́ Ìkẹ́yìn, kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn t’ó bá yapa Allāhu àti Òjíṣẹ́ Rẹ̀ kódà kí wọ́n jẹ́ àwọn bàbá wọn, tàbí àwọn ọmọ wọn tàbí àwọn arákùnrin wọn tàbí àwọn ìbátan wọn. Àwọn wọ̀nyẹn ni Allāhu ti kọ ìgbàgbọ́ òdodo sínú ọkàn wọn. Allāhu sì kún wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ (al-Ƙur’ān àti ìṣẹ́gun) láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó sì máa mú wọn wọ inú àwọn Ọgbà Ìdẹ̀ra, èyí tí àwọn odò ń ṣàn ní ìsàlẹ̀ rẹ̀. Olùṣegbére ni wọ́n nínú rẹ̀. Allāhu yọ́nú sí wọn. Wọ́n sì yọ́nú sí (ohun tí Allāhu fún wọn). Àwọn wọ̀nyẹn ni ìjọ Allāhu. Gbọ́! Dájúdájú ìjọ Allāhu, àwọn ni olùjèrè.
____________________
Ẹ wo ìtọsẹ̀-ọ̀rọ̀ fún sūrah at-Taobah; 9:23.
سورة المجادلة
معلومات السورة
الكتب
الفتاوى
الأقوال
التفسيرات

سورة (المجادلة) من السُّوَر المدنية، نزَلتْ لتحريم عادةٍ من عادات الجاهلية؛ وهي (الظِّهار)، وذلك في حادثةِ مظاهرة أوسِ بن الصامت مِن زوجِه خَوْلةَ، وقد جاءت السورةُ بمقصدٍ عظيم؛ وهو إثبات علمِ الله، وإحاطتِه بكل شيء، ومِن كمال ألوهيته سبحانه: الحُكْمُ العدل فيما يصلُحُ لهم من الشرائع، وخُتمت السورة ببيان حال أعداء الله، وحالِ أوليائه.

ترتيبها المصحفي
58
نوعها
مدنية
ألفاظها
475
ترتيب نزولها
105
العد المدني الأول
28
العد المدني الأخير
28
العد البصري
29
العد الكوفي
29
العد الشامي
28

* قوله تعالى: {قَدْ سَمِعَ اْللَّهُ قَوْلَ اْلَّتِي تُجَٰدِلُكَ فِي زَوْجِهَا وَتَشْتَكِيٓ إِلَى اْللَّهِ وَاْللَّهُ يَسْمَعُ تَحَاوُرَكُمَآۚ إِنَّ اْللَّهَ سَمِيعُۢ بَصِيرٌ} [المجادلة: 1]:

عن عائشةَ أمِّ المؤمنين رضي الله عنها، قالت: «الحمدُ للهِ الذي وَسِعَ سَمْعُه الأصواتَ، لقد جاءت خَوْلةُ إلى رسولِ اللهِ صلى الله عليه وسلم تشكو زوجَها، فكان يَخفَى عليَّ كلامُها؛ فأنزَلَ اللهُ عز وجل: {قَدْ سَمِعَ اْللَّهُ قَوْلَ اْلَّتِي تُجَٰدِلُكَ فِي زَوْجِهَا} [المجادلة: 1] إلى آخرِ الآيةِ». أخرجه النسائي (٣٤٦٠)، وابن ماجه (١٨٨).

* قوله تعالى: {وَإِذَا جَآءُوكَ حَيَّوْكَ بِمَا لَمْ يُحَيِّكَ بِهِ اْللَّهُ} [المجادلة: 8]:

عن عبدِ اللهِ بن عمرٍو رضي الله عنهما، قال: «إنَّ اليهودَ كانوا يقولون لرسولِ اللهِ ﷺ: سامٌ عليك! ثم يقولون في أنفسِهم: {لَوْلَا يُعَذِّبُنَا اْللَّهُ بِمَا نَقُولُۚ} [المجادلة: 8]؛ فنزَلتْ هذه الآيةُ: {وَإِذَا جَآءُوكَ حَيَّوْكَ بِمَا لَمْ يُحَيِّكَ بِهِ اْللَّهُ} [المجادلة: 8] إلى آخرِ الآيةِ». أخرجه أحمد (٦٥٨٩).

* قوله تعالى: {وَيَحْلِفُونَ عَلَى اْلْكَذِبِ وَهُمْ يَعْلَمُونَ} [المجادلة: 14]:

عن عبدِ اللهِ بن عباسٍ رضي الله عنهما، قال: «قال رسولُ اللهِ صلى الله عليه وسلم: «يدخُلُ عليكم رجُلٌ ينظُرُ بعينِ شيطانٍ، أو بعَيْنَيْ شيطانٍ»، قال: فدخَلَ رجُلٌ أزرَقُ، فقال: يا مُحمَّدُ، علامَ سبَبْتَني -أو: شتَمْتَني، أو نحوَ هذا-؟ قال: وجعَلَ يَحلِفُ، قال: فنزَلتْ هذه الآيةُ في المجادلةِ: {وَيَحْلِفُونَ عَلَى اْلْكَذِبِ وَهُمْ يَعْلَمُونَ} [المجادلة: 14]، والآيةُ الأخرى». أخرجه أحمد (٢١٤٧).

قال محقِّقو "المسند" (4 /48): «قوله: «فقال: يا مُحمَّدُ، علامَ سبَبْتَني؟»؛ كذا جاء في جميع الأصول، وكذلك هو في "مسند البزار"، وزيادة: «يا محمد» - كما قال الشيخُ أحمد شاكر- خطأٌ ينافي السياق؛ فإن الذي نُسِب إليه السبُّ والشَّتم هنا هو المنافقُ الأزرق، ورسولُ الله يَسأله ويتَّهِمُه، وهو يَحلِف كاذبًا يَتبرَّأ من التُّهمة، وقد جاء في "تفسير الطبري" على الصواب بإسقاطِ هذه الزيادة، وسيأتي على الصواب أيضًا عند أحمد (2407)»، انظر السبب الآتي.

* قوله تعالى: {يَوْمَ يَبْعَثُهُمُ اْللَّهُ جَمِيعٗا فَيَحْلِفُونَ لَهُۥ كَمَا يَحْلِفُونَ لَكُمْ وَيَحْسَبُونَ أَنَّهُمْ عَلَىٰ شَيْءٍۚ أَلَآ إِنَّهُمْ هُمُ اْلْكَٰذِبُونَ} [المجادلة: 18]:

عن سعيدِ بن جُبَيرٍ، أنَّ ابنَ عباسٍ رضي الله عنهما حدَّثه، قال: «كان رسولُ اللهِ صلى الله عليه وسلم في ظلِّ حُجْرةٍ مِن حُجَرِه، وعنده نَفَرٌ مِن المسلمين، قد كاد يَقلِصُ عنهم الظِّلُّ، قال: فقال: «إنَّه سيأتيكم إنسانٌ ينظُرُ إليكم بعَيْنَيْ شيطانٍ، فإذا أتاكم، فلا تُكلِّموه»، قال: فجاء رجُلٌ أزرَقُ، فدعاه رسولُ اللهِ صلى الله عليه وسلم، فكلَّمَه، قال: «علامَ تَشتِمُني أنتَ، وفلانٌ، وفلانٌ؟»، نَفَرٌ دعَاهم بأسمائهم، قال: فذهَبَ الرَّجُلُ، فدعَاهم، فحلَفوا باللهِ واعتذَروا إليه، قال: فأنزَلَ اللهُ عز وجل: {فَيَحْلِفُونَ لَهُۥ كَمَا يَحْلِفُونَ لَكُمْ وَيَحْسَبُونَ ...} [المجادلة: 18] الآيةَ» أخرجه أحمد (2407).

* سورةُ (المجادلة):

سُمِّيت سورةُ (المجادلة) بهذا الاسم؛ لافتتاحها بقصَّة مجادلةِ امرأةِ أوس بن الصامت عند النبي صلى الله عليه وسلم.

وتُسمَّى كذلك بـ (قَدْ سَمِعَ)؛ لافتتاحها بهذا اللفظِ.

1. الظِّهار وكفَّارته (١-٤).

2. خَسارة مَن عادى اللهَ، وتعدَّى حدوده (٥-١٩).

3. حال أعداء الله، ومدحُ أوليائه (٢٠-٢٢).

ينظر: "التفسير الموضوعي لسور القرآن الكريم" لمجموعة من العلماء (8 /34).

يقول ابنُ عاشور رحمه الله عن مقصد السورةِ: «الحُكْمُ في قضيَّة مظاهرة أوسِ بن الصامت من زوجه خَوْلة.
وإبطالُ ما كان في الجاهلية من تحريم المرأة إذا ظاهَر منها زوجُها، وأن عملهم مخالفٌ لِما أراده الله، وأنه من أوهامهم وزُورِهم التي كبَتَهم اللهُ بإبطالها، وتخلَّصَ من ذلك إلى ضلالاتِ المنافقين؛ ومنها مناجاتُهم بمرأى المؤمنين ليَغِيظوهم ويحزُنوهم.
ومنها موالاتهم اليهودَ، وحَلِفُهم على الكذب، وتخلَّل ذلك التعرُّض لآداب مجلس الرسول صلى الله عليه وسلم.

وشرع التصدُّق قبل مناجاة الرسول صلى الله عليه وسلم.

والثناء على المؤمنين في مجافاتهم اليهودَ والمشركين.

وأن اللهَ ورسوله وحِزْبَهما هم الغالبون». "التحرير والتنوير" لابن عاشور (28 /6).